Isaiah 65:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí inú yín ó máa dùn, kí ẹ sì máa yọ títí lae, ninu ohun tí mo dá. Wò ó! Mo dá Jerusalẹmu ní ìlú aláyọ̀, mo sì dá àwọn eniyan inú rẹ̀ ní onínú dídùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ki ẹnyin ki o yọ̀, ki inu nyin ki o si dùn titi lai ninu eyi ti emi o da: nitori kiyesi i, emi o da Jerusalemu ni inudidùn, ati awọn enia rẹ̀ ni ayọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá, nítorí èmi yóò dá Jérúsálẹ́mù láti jẹ́ ohun ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀.