Isaiah 65:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọmọ tuntun kò ní kú ní Jerusalẹmu mọ́, àwọn àgbààgbà kò sì ní kú láìjẹ́ pé wọ́n darúgbó kùjọ́kùjọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ikú ọ̀dọ́ ni a óo máa pe ikú ẹni tí ó bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún. Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún, a óo sọ pé ó kú ikú ègún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki yio si ọmọ-ọwọ nibẹ ti ọjọ rẹ̀ kì yio pẹ́, tabi àgba kan ti ọjọ rẹ̀ kò kún: nitori ọmọde yio kú li ọgọrun ọdun; ṣugbọn ẹlẹṣẹ ọlọgọrun ọdun yio di ẹni-ifibu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀, tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán; ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún ni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé; ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kan ni a ó pè ní ẹni ìfibú.