Isaiah 65:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn kò ní kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé, wọn kò sì ní gbin ọgbà àjàrà fún ẹlòmíràn jẹ. Àwọn eniyan mi yóo pẹ́ láyé bí igi ìrókò, àwọn àyànfẹ́ mi yóo sì jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn kì yio kọ ile fun ẹlomiran lati gbé, nwọn kì yio gbìn fun ẹlomiran lati jẹ: nitori gẹgẹ bi ọjọ igi li ọjọ awọn enia mi ri, awọn ayanfẹ mi yio si jìfà iṣẹ ọwọ́ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmìíràn láti gbé, tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmìíràn láti jẹ, Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan, bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún ìgbà pípẹ́.