Isaiah 65:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn kò ní ṣe iṣẹ́ àṣedànù, wọn kò ní bímọ fún jamba; nítorí ọmọ ẹni tí OLUWA bukun ni wọn yóo jẹ́, àwọn ati àwọn ọmọ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn kì yio ṣiṣẹ lasan, nwọn kì yio bimọ fun wahala: nitori awọn ni iru alabukun Oluwa ati iru-ọmọ wọn pẹlu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn kì yóò ṣe wàhálà lásán tàbí kí wọn bímọ tí ọjọ́ iwájú wọn kì yóò sunwọ̀n; nítorí wọn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn ti OLÚWA bùkún fún, àwọn àti àwọn ìrandíran wọn pẹ̀lú wọn.