Isaiah 65:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìkookò ati ọmọ aguntan yóo jọ máa jẹ káàkiri; kinniun yóo máa jẹ koríko bíi mààlúù, erùpẹ̀ ni ejò yóo máa jẹ, wọn kò ní máa panilára. Wọn kò sì ní máa panirun lórí òkè mímọ́ mi mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ikõko ati ọdọ-agutan yio jumọ jẹ pọ̀, kiniun yio si jẹ koriko bi akọ-mãlu: erupẹ ni yio jẹ onjẹ ejò. Nwọn kì yio panilara, tabi ki nwọn panirun ni gbogbo oke mimọ́ mi, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn yóò jẹun pọ̀, kìnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù, ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò. Wọn kì yóò panilára tàbí panirun ní gbogbo òkè mímọ́ mi,” ni OLÚWA wí.