Isaiah 65:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn á máa ké pé, “Yàgò lọ́nà. Má fara kàn mí, nítorí mo jẹ́ ẹni mímọ́ jù ọ́ lọ.” Ṣugbọn bí èéfín ni irú wọn rí ní ihò imú mi, bí iná tí ó ń jó lojoojumọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o wipe, Duro fun ara rẹ, máṣe sunmọ mi; nitori ti mo ṣe mimọ́ jù ọ lọ. Wọnyi li ẹ̃fin ni imu mi, iná ti njo ni gbogbo ọjọ ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
tí ó wí pé, ‘Ẹ sún mẹ́yìn; ẹ má wá sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti jẹ́ mímọ́ jù fún un yín!’ Àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èéfín nínú ihò imú mi iná tí ń fi gbogbo ọjọ́ jó.