Isaiah 65:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo gbẹ̀san gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lára wọn, ati ti àwọn baba wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí pé wọ́n ń sun turari lórí àwọn òkè ńlá, wọ́n sì ń fi mí ṣẹ̀sín lórí àwọn òkè kéékèèké. N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn àtẹ̀yìnwá fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Aiṣedede nyin, ati aiṣedede awọn baba nyin ṣọkan pọ̀, li Oluwa wi, awọn ẹniti o fi turari jona lori oke-nla, ti nwọn mbu ọla mi kù lori awọn oke kékèké: nitori na li emi o wọ̀n iṣẹ wọn iṣaju, sinu aiya wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín àti tàwọn baba yín,” ni OLÚWA wí. “Nítorí pé wọ́n sun ẹbọ ní orí òkè ńlá wọ́n sì ṣe mí lẹ́gbin ní òkè kékeré, Èmi yóò wọ́n ọ́n sí wọn nítan ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀san ohun gbogbo tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀.”