Isaiah 65:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí eniyan tíí wòye pé ọtí wà lára ìdì èso àjàrà, tí wọn sìí sọ pé, ‘Ẹ má bà á jẹ́, nítorí ohun rere wà ninu rẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe nítorí iranṣẹ mi, n kò ní pa gbogbo wọn run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Oluwa wi, gẹgẹ bi a ti iri ọti-waini titun ninu ìdi eso àjara, ti a si nwipe, Máṣe bà a jẹ nitori ibukun mbẹ ninu rẹ̀: bẹ̃li emi o ṣe nitori awọn iranṣẹ mi, ki emi ki o má ba pa gbogbo wọn run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun tí OLÚWA wí nìyìí: “Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí òjé sì tún wà nínú àpólà gírépù tí àwọn ènìyàn sì wí pé, ‘má ṣe bà á jẹ́, ohun dáradára sì kù sínú rẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí ìránṣẹ́ mi; Èmi kì yóò pa gbogbo wọn run.