Isaiah 65:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo mú kí arọmọdọmọ jáde lára Jakọbu, àwọn tí yóo jogún òkè ńlá mi yóo sì jáde láti ara Juda. Àwọn tí mo ti yàn ni yóo jogún rẹ̀, àwọn iranṣẹ mi ni yóo sì máa gbé ibẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si mu iru kan jade ni Jakobu, ati ajogun oke-nla mi lati inu Juda: ayanfẹ mi yio si jogun rẹ̀, awọn iranṣẹ mi yio si gbe ibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jákọ́bù, àti láti Júdà àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n ọn nì; àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn, ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé.