Isaiah 66:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ẹ lè mu àmutẹ́rùn, ninu wàrà rẹ̀ tí ń tuni ninu; kí ẹ lè ní ànítẹ́rùn pẹlu ìdùnnú, ninu ọpọlọpọ ògo rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o le mu ọmú, ki a si fi ọmú itunu rẹ̀ tẹ́ nyin lọrùn; ki ẹnyin ki o ba le fun wàra, ki inu nyin ba sì le dùn si ọ̀pọlọpọ ogo rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ọmú rẹ̀ tí ó túnilára; Ẹ̀yin yóò mu àmuyó ẹ ó sì gbádùn nínú à-kún-wọ́-sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”