Isaiah 66:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí OLUWA ní: “N óo tú ibukun sórí rẹ̀, bí ìgbà tí odò bá ń ṣàn. N óo da ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́, bí odò tí ò ṣàn kọjá bèbè. Yóo dà yín sẹ́gbẹ̀ẹ́ bí ọmọ tí ń mu ọmú, ẹ óo máa ṣeré lórí orúnkún rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o nà alafia si i bi odò, ati ogo awọn Keferi bi odò ṣiṣàn: nigbana li ẹnyin o mu ọmú, a o dà nyin si ẹgbẹ́ rẹ̀, a o si ma gbe nyin jo lori ẽkún rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ohun tí OLÚWA wí nìyìí: “Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odò àti ọrọ̀ orílẹ̀ èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi; ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀ a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.