Isaiah 66:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ óo rí i, inú yín yóo dùn, egungun yín yóo sọjí, bí ìgbà tí koríko bá rúwé. Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé ọwọ́ OLUWA wà lára àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati pé inú bí i sí àwọn ọ̀tá rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ẹnyin ba ri eyi, ọkàn nyin yio yọ̀, egungun nyin yio si tutu yọ̀yọ bi ewebẹ̀; a o si mọ̀ ọwọ́ Oluwa lara awọn iranṣẹ rẹ̀, ati ibinu rẹ̀ si awọn ọta rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú un yín yóò dùn ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko; ọwọ́ OLÚWA ni a ó sọ di mímọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.