Isaiah 66:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wò ó! OLUWA ń bọ̀ ninu iná, kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ yóo dàbí ìjì, láti fi ìrúnú san ẹ̀san, yóo sì fi ahọ́n iná báni wí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori kiyesi i, Oluwa mbọ wá ti on ti iná, ati awọn kẹkẹ́ rẹ̀ bi ãjà, lati fi irunu sẹsan ibinu rẹ̀, ati ibawi rẹ̀ nipa ọwọ́ iná.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kíyèsí i, OLÚWA ń bọ̀ pẹ̀lú iná àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle; òun yóò mú ìbínú rẹ ṣọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú, àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná.