Isaiah 66:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀, tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n ń lọ bọ̀rìṣà ninu àgbàlá, wọ́n ń jó ijó oriṣa, wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀, ati àwọn ohun ìríra, ati èkúté! Gbogbo wọn ni yóo ṣègbé papọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ti o yà ara wọn si mimọ́, ti nwọn si sọ ara wọn di mimọ́ ninu agbala wọnni, ti ọkan tẹle ekeji li ãrin, nwọn njẹ ẹran ẹlẹdẹ, ati ohun irira, ati eku, awọn li a o parun pọ̀; li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrin àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀,” ni OLÚWA wí.