Isaiah 66:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí mo mọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn ati èrò ọkàn wọn. Mò ń bọ̀ wá gbá gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà jọ. Nígbà tí wọ́n bá dé, wọ́n óo rí ògo mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi mọ̀ iṣẹ ati ìro wọn: igba na yio dé lati ṣà gbogbo awọn orilẹ-ède ati ahọn jọ, nwọn o si wá, nwọn o si ri ogo mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àti Èmi, nítorí ìgbéṣẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn òrílẹ̀ èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi.