Isaiah 66:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“N óo sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrin wọn. N óo rán àwọn tí ó yè lára wọn sí àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn bíi: Taṣiṣi, Puti, ati Ludi, ilẹ̀ àwọn tafàtafà, ati Tubali ati Jafani, ati àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré; àwọn tí kò tíì gbọ́ òkìkí mi, tí wọn kò sì tíì rí ògo mi rí. Wọn óo sì ròyìn ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si fi àmi kan si ãrin wọn, emi o si rán awọn ti o salà ninu wọn si awọn orilẹ-ède, si Tarṣiṣi, Puli, ati Ludi, awọn ti nfà ọrun, si Tubali, on Jafani, si awọn erekuṣu ti o jina rére, ti nwọn kò ti igbọ́ okiki mi, ti nwọn kò si ti iri ogo mi; nwọn o si rohin ogo mi lãrin awọn Keferi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi yóò sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrin wọn, èmi yóò sì rán díẹ̀ nínú àwọn tí ó sálà lọ sí àwọn orílẹ̀ èdè Táṣíṣì, sí àwọn ará Líbíyà àti Lídíyà (ti a mọ̀ sí atamọ́tàsé), sí Túbálì ati ará Gíríkì, àti sí àwọn erékùṣù tí ó jìnnàréré tí kò tí ìgbọ́ nípa òkìkí mi tàbí kí ó rí ògo mi. Wọn yóò kéde ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè.