Isaiah 66:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọwọ́ mi ni mo fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi, tèmi sì ni gbogbo wọn. Ẹni tí n óo kà kún, ni onírẹ̀lẹ̀ ati oníròbìnújẹ́ eniyan, tí ó ń wárìrì nítorí ọ̀rọ̀ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori gbogbo nkan wọnni li ọwọ́ mi sa ti ṣe, gbogbo nkan wọnni si ti wà, li Oluwa wi: ṣugbọn eleyi li emi o wò, ani òtoṣi ati oniròbinujẹ ọkàn, ti o si nwarìri si ọ̀rọ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà?” ni OLÚWA wí. “Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí: ẹni náà tí ó rẹrarẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀, tí ó sì wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi.