Isaiah 66:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn óo sì kó gbogbo àwọn ará yín bọ̀ láti orílẹ̀-èdè gbogbo, wọn óo kó wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA. Wọn óo máa bọ̀ lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́-ogun, lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí, wọn óo máa wá sí ìlú Jerusalẹmu, òkè mímọ́ mi, bí àwọn ọmọ Israẹli yóo ti máa mú ẹbọ ohun jíjẹ wọn wá sí ilé OLUWA, ninu àwo tí ó mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si mu gbogbo awọn arakunrin nyin lati orilẹ-ède gbogbo wá, ẹbọ kan si Oluwa lori ẹṣin, ati ninu kẹkẹ́, ati ninu páfa, ati lori ibaka, ati lori rakunmi, si Jerusalemu oke-nla mimọ́ mi; li Oluwa wi, gẹgẹ bi awọn ọmọ Israeli ti imu ọrẹ wá ninu ohun-elò mimọ́ sinu ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀ èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí OLÚWA lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti wágùnnù, àti lórí ìbáaka àti ràkúnmí,” ni OLÚWA wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú tẹ́ḿpìlì OLÚWA nínú ohun èlò mímọ́.