Isaiah 66:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ati ẹni tí ó pa mààlúù rúbọ, ati ẹni tí ó pa eniyan; kò sí ìyàtọ̀. Ẹni tí ó fi ọ̀dọ́ aguntan rúbọ, kò yàtọ̀ sí ẹni tí ó lọ́ ajá lọ́rùn pa. Ati ẹni tí ó fi ọkà rúbọ, ati ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ, bákan náà ni wọ́n rí. Ẹni tí ó fi turari ṣe ẹbọ ìrántí, kò sì yàtọ̀ sí ẹni tí ó súre níwájú oriṣa. Wọ́n ti yan ọ̀nà tí ó wù wọ́n, wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn sin ohun ìríra wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o pa akọ-malu, o dabi ẹnipe o pa enia; ẹniti o fi ọdọ-agutan rubọ, a dabi ẹnipe o bẹ́ ajá lọrùn; ẹniti o rubọ ọrẹ, bi ẹnipe o fi ẹ̀jẹ ẹlẹdẹ̀ rubọ; ẹniti o fi turari jona, bi ẹniti o sure fun òriṣa. Nitotọ, nwọn ti yàn ọ̀na ara wọn, inu wọn si dùn si ohun iríra wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi akọ màlúù rúbọ ó dàbí ẹni tí ó pa ènìyàn kan àti ẹni tí ó bá fi ọ̀dọ́ àgùntàn kan tọrẹ, dàbí ẹni tí ó kán ajá kan lọ́rùn; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi irúgbin oníhóró tọrẹ dàbí ẹni tí ó mú ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ wá, ẹni tí ó bá sì ṣun tùràrí ìrántí, dàbí ẹni tí ó sin ère òrìṣà. Wọ́n ti yan ipa ọ̀nà tiwọn, ọkàn wọn pẹ̀lú sì láyọ̀ nínú ohun ìríra wọn;