Isaiah 66:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Èmi náà óo sì yan ìjìyà fún wọn, n óo jẹ́ kí ẹ̀rù wọn pada sórí wọn. Nítorí pé nígbà tí mo pè wọ́n, ẹnikẹ́ni wọn kò dáhùn; nígbà tí mo sọ̀rọ̀ fún wọn, wọn kò gbọ́, wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú mi, wọ́n yan ohun tí inú mi kò dùn sí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi pẹlu yio yàn itanjẹ wọn, emi o si mu eyi ti nwọn bẹ̀ru wá sara wọn, nitori nigbati mo pè, kò si ẹnikan ti o dahùn; nigbati mo sọ̀rọ, nwọn kò gbọ́: ṣugbọn nwọn ṣe buburu niwaju mi, nwọn si yàn eyiti inu mi kò dùn si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọn n ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn. Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn, nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tísílẹ̀. Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú mi wọ́n sì yan ohun tí mo kóríìra rẹ̀.”