Isaiah 66:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wárìrì nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Àwọn arakunrin yín tí wọn kórìíra yín, wọ́n tì yín síta nítorí orúkọ mi; wọ́n ní, ‘Jẹ́ kí OLUWA fi ògo rẹ̀ hàn, kí á lè rí ayọ̀ yín.’ Ṣugbọn àwọn ni ojú yóo tì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ti o nwarìri si ọ̀rọ rẹ̀; Awọn arakunrin nyin ti nwọn korira nyin, ti nwọn ta nyin nù nitori orukọ mi, wipe, Jẹ ki a fi ogo fun Oluwa: ṣugbọn on o fi ara hàn fun ayọ̀ nyin, oju yio si tì awọn na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA, Ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípaṣẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kóríra yín, tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé, ‘Jẹ́ kí a yin OLÚWA lógo, kí a le rí ayọ̀ yín!’ Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì.