Isaiah 66:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ta ló gbọ́ irú èyí rí? Ta ló rí irú rẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a lè bí ilẹ̀ ní ọjọ́ kan, tabi kí á bí orílẹ̀-èdè kan ní ọjọ́ kan? Ní kété tí Sioni bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, ni ó bí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tali o ti igbọ́ iru eyi ri? tali o ti iri irú eyi ri? Ilẹ le hù nkan jade li ọjọ kan bi? tabi a ha le bi orilẹ-ède ni ọjọ́ kan nã? nitori bi Sioni ti nrọbi gẹ, bẹ̃li o bi awọn ọmọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀ èdè kan níjọ́ kan tàbí kí orílẹ̀ èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan? Síbẹ̀síbẹ̀ Ṣíhónì bẹ̀rẹ̀ rírọbí tàìrọbí bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀.