Isaiah 7:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà ayé Ahasi, ọmọ Jotamu, ọmọ Usaya, ọba Juda, Resini Ọba Siria ati Peka ọmọ Remalaya, ọba Israẹli wá gbé ogun ti Jerusalẹmu, ṣugbọn wọn kò lè ṣẹgun rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li ọjọ Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah, ọba Juda, ti Resini, ọba Siria, ati Peka ọmọ Remaliah, ọba Israeli, gokè lọ si Jerusalemu lati jà a li ogun, ṣugbọn nwọn kò le bori rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Áhásì ọmọ Jótamù ọmọ Hùṣáyà jẹ́ ọba Júdà, ọba Résínì ti Árámù àti Pẹ́kà ọmọ Rẹ̀málíà ọba Ísírẹ́lì gòkè wá láti bá Jérúsálẹ́mù jà, ṣùgbọ́n wọn kò sì le è borí i rẹ̀.