Isaiah 7:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ìròyìn dé ilé ọba Dafidi pé àwọn ará Siria ati Efuraimu ń gbógun bọ̀, ọkàn òun ati àwọn eniyan rẹ̀ mì tìtì bí afẹ́fẹ́ tíí mi igi ninu igbó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si sọ fun ile Dafidi pe, Siria ba Efraimu dìmọlú. Ọkàn rẹ̀ si mì, ati ọkàn awọn enia rẹ̀ bi igi igbo ti imì nipa ẹfũfu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí, a sọ fún ilé Dáfídì pé, “Árámù mà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Éfáímù”; fún ìdí èyí, ọkàn Áhásì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wárìrì gẹ́gẹ́ bí igi oko ṣe ń wárìrì níwájú afẹ́fẹ́.