Isaiah 7:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo ara òkè tí wọn tí ń fi ọkọ́ ro tẹ́lẹ̀, ẹnikẹ́ni kò ní lè débẹ̀ mọ́, nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn, gbogbo ibẹ̀ yóo wá di ibi tí mààlúù ati aguntan yóo ti máa jẹko.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lori gbogbo okè kékèké ti a o fi ọkọ́ tu, ẹ̀ru ẹ̀wọn ati ẹ̀gun ki yio de ibẹ̀: ṣugbọn yio jẹ ilu ti a ndà malũ lọ, ati ibi itẹ̀mọlẹ fun awọn ẹran kékèké.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún àwọn òkè tí a ti ń fi ọkọ́ ro nígbà kan rí, ẹ kò ní lọ ṣíbẹ̀ mọ́ nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n, wọn yóò di ibi tí a ń tú agbo ẹran sí, àti ibi tí àwọn àgùntàn ti ń sáré.