Isaiah 7:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí o sọ fún un pé, ṣọ́ra, farabalẹ̀, má sì bẹ̀rù. Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ já rárá nítorí ibinu gbígbóná Resini ati Siria, ati ti ọmọ Remalaya, nítorí wọn kò yàtọ̀ sí àjókù igi iná meji tí ń rú èéfín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si sọ fun u pe, Kiyesara, ki o si gbe jẹ, má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki o máṣe jaiya nitori ìru meji igi iná ti nrú ẹ̃fin wọnyi nitori ibinu mimuna Resini pẹlu Siria, ati ti ọmọ Remaliah.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sọ fún un, ‘Ṣọ́ra à rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o má ṣe bẹ̀rù. Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítoríi kùkùté igi ìdáná méjèèjì yìí, nítorí ìbínú gbígbóná Résínì àti Árámù àti ti ọmọ Rẹ̀málíà.