Isaiah 7:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣebí Damasku ni olú-ìlú Siria, Resini sì ni olórí Damasku. Láàrin ìsinyìí sí ọdún marundinlaadọrin, Efuraimu yóo fọ́nká, kò sì ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ori Siria ni Damasku, ori Damasku si ni Resini; ninu ọdun marunlelọgọta li a o fọ Efraimu ti ki yio si jẹ́ enia mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nítorí Dámásíkù ni orí Árámù, orí Dámásíkù sì ni Résínì. Láàrin ọdún márùnlélọ́gọ́ta Éfáímù yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́.