Isaiah 8:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo di ibi-mímọ́ ati òkúta ìdìgbòlù, ati àpáta tí ó ń mú kí eniyan kọsẹ̀, fún ilẹ̀ Israẹli mejeeji. Yóo di ẹ̀bìtì ati tàkúté fún àwọn ará Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On o si wà fun ibi mimọ́, ṣugbọn fun okuta idùgbolu, ati fun apata ẹ̀ṣẹ, si ile Israeli mejeji, fun ẹgẹ, ati fun okùn didẹ si awọn ara Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́ ṣùgbọ́n fún ilé Ísírẹ́lì méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọṣẹ̀ àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú àti fún àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ni yóò jẹ́ tàkúté àti ẹ̀bìtì.