Isaiah 8:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ wò ó! Èmi ati àwọn ọmọ tí OLUWA fún mi, a wà fún àmì ati ìyanu ní Israẹli láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí ń gbé orí òkè Sioni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, emi ati awọn ọmọ ti Oluwa ti fi fun mi wà fun àmi ati fun iyanu ni Israeli, lati ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ti ngbe òke Sioni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi nìyí, àti àwọn ọmọ tí OLÚWA fi fún mi. Àwa jẹ́ àmì àti àpẹẹrẹ ní Ísírẹ́lì láti ọ̀dọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, ẹni tí ó ń gbé ní òké Síhónì.