Isaiah 8:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn yóo kọjá lọ lórí ilẹ̀ náà ninu ìnira ati ebi; nígbà tí ebi bá pa wọ́n, wọn yóo máa kanra, wọn óo gbé ojú wọn sókè, wọn óo sì gbé ọba ati Ọlọrun wọn ṣépè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si kọja lọ lãrin rẹ̀, ninu inilara ati ebi: yio si ṣe pe nigbati ebi yio pa wọn, nwọn o ma kanra, nwọn o si fi ọba ati Ọlọrun wọn re, nwọn o si ma wò òke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú ìpọ́njú àti ebi, ni wọn yóò máa rin ilẹ̀ náà ká, nígbà tí ebi bá pa wọ́n, nígbà yìí ni inú yóò bí wọn, wọn yóò síjú wòkè, wọn yóò sì ṣépè lé àwọn ọba àti ọlọ́run wọn.