Isaiah 9:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣé bíríkì ni wọ́n fi kọ́ àwọn ilé tí ó wó lulẹ̀? Òkúta gbígbẹ́ ni a óo fi tún wọn kọ́. Igi sikamore ni a fi kọ́ èyí tí wọ́n dà wó, ṣugbọn igi kedari dáradára ni a óo lò dípò wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Briki wọnni ṣubu lu ilẹ, ṣugbọn awa o fi okuta gbigbẹ́ mọ ọ: a ke igi sikamore lu ilẹ, ṣugbọn a o fi igi kedari pãrọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀ ṣùgbọ́n a ó tún un kọ́ pẹ̀lú òkúta dídán, a ti gé àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ lulẹ̀ ṣùgbọ́n igi kédárì ní a ó fí dípò wọn.