Isaiah 9:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA kò láyọ̀ lórí àwọn ọdọmọkunrin wọn, àánú àwọn aláìníbaba ati àwọn opó wọn kò sì ṣe é nítorí pé aṣebi ni gbogbo wọn, wọn kò sì mọ Ọlọrun, ọ̀rọ̀ burúkú ni wọ́n sì ń fi ẹnu wọn sọ. Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni Oluwa kì yio ṣe ni ayọ̀ ninu ọdọ-ọmọkunrin wọn, bẹ̃ni ki yio ṣãnu fun awọn alainibaba ati opo wọn: nitori olukuluku wọn jẹ agabagebe ati oluṣe-buburu, olukuluku ẹnu nsọ wère. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, OLÚWA kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó, nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ́ Ọlọ́run, ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde. Ṣíbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò ọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.