Isaiah 9:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìwà burúkú wọn ń jó bí iná, tí ń jó ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn. Ó ń jó bíi igbó ńlá, ó sì ń yọ èéfín sókè lálá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ìwa-buburu njo bi iná: yio jo ẹwọn ati ẹgún run, yio si ràn ninu pàntiri igbó, nwọn o si goke lọ bi ẹ̃fin iti goke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítòótọ́ ìkà ń jóni bí iná, ó ń jó àtẹ̀wọ̀n, àtẹ̀gùn run, ó sì ń dáná sun ìgbẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ń yí lọ sókè ní ọ̀wọ̀n èéfín.