Isaiah 9:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun, ilẹ̀ náà jóná, àwọn eniyan ibẹ̀ dàbí èpò tí a dà sinu iná ẹnikẹ́ni kò sì dá ẹnìkejì rẹ̀ sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nipa ibinu Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ilẹ fi ṣõkùn, awọn enia yio dabi igi iná, ẹnikan kì yio dá arakunrin rẹ̀ si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípaṣẹ̀ ìbínú OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ náà yóò di gbígbẹ àwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná, ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí.