Isaiah 9:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará Manase ń bá àwọn ará Efuraimu jà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Efuraimu náà ń bá àwọn ará Manase jà. Àwọn mejeeji wá dojú ìjà kọ Juda. Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò dáwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Manasse o jẹ Efraimu; Efraimu o si jẹ Manasse: awọn mejeji o dojukọ Juda. Ni gbogbo eyi, ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mánásè yóò máa jẹ Éfáímù, nígbà tí Éfáímù yóò jẹ Mánásè wọn yóò parapọ̀ dojúkọ Júdà. Ṣíbẹ̀síbẹ̀, ìbínú un rẹ̀ kò yí kúrò Ọwọ́ọ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.

Recommended Reading