James 1:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí nígbà tí oòrùn bá yọ, tí ó mú, koríko á rọ, òdòdó rẹ̀ á sì rẹ̀, òdòdó tí ó lẹ́wà tẹ́lẹ̀ á wá ṣègbé. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ọlọ́rọ̀ yóo parẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori õrun là ti on ti õru mimu, o si gbẹ koriko, itanná rẹ̀ si rẹ̀ danu, ẹwà oju rẹ̀ si parun: bẹ̃ pẹlu li ọlọrọ̀ yio ṣegbe ni ọ̀na rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí oòrùn là ti òun ti ooru mímú ó sì gbẹ́ koríko, ìtànná rẹ̀ sì rẹ̀ dànú, ẹwà ojú rẹ̀ sì parun: bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ọlọ́rọ̀ yóò ṣègbé ní ọ̀nà rẹ̀.