James 1:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn olúwarẹ̀ níláti bèèrè pẹlu igbagbọ, láì ṣiyèméjì. Nítorí ẹni tí ó bá ń ṣiyèméjì dàbí ìgbì omi òkun, tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri tí ó sì ń rú sókè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ki o bère ni igbagbọ́, li aiṣiyemeji rara. Nitori ẹniti o nṣiyemeji dabi ìgbi omi okun, ti nti ọwọ́ afẹfẹ bì siwa bì sẹhin ti a si nrú soke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá bèèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá. Nítorí ẹni tí ó ń sé iyè méjì dàbí ìgbì omi òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè.