James 2:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ẹ óo máa fi ojurere wo ẹni tí ó wọ aṣọ dídán, ẹ óo sọ fún un pé, “Wá jókòó níbi dáradára yìí.” Ṣugbọn ẹ óo wá sọ fún talaka pé, “Dúró níbẹ̀, tabi wá jókòó nílẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ mi níhìn-ín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti ẹnyin si bu iyìn fun ẹniti o wọ̀ aṣọ daradara, ti ẹ si wipe, Iwọ joko nihinyi ni ibi daradara; ti ẹ si wi fun talakà na pe, Iwọ duro nibẹ̀, tabi joko nihin labẹ apoti itisẹ mi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tí ẹ̀yin sì bu ọla fún ẹni tí ó wọ aṣọ dáradára tí ẹ sì wí pé, “Ìwọ jókòó níhìn-ín yìí ní ibi dáradára” tí ẹ sì wí fún talákà náà pé, “Ìwọ dúró níbẹ̀” tàbí “jókòó níhìn-ín lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi;”