James 3:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Iná ni ahọ́n. Ó kún fún àwọn nǹkan burúkú ayé yìí. Ninu àwọn ẹ̀yà ara wa, ahọ́n ni ó ń kó nǹkan ibi bá gbogbo ara. A máa mú kí gbogbo ara wá gbóná, iná ọ̀run àpáàdì ni ó túbọ̀ ń fún un ní agbára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iná si ni ahọ́n, aiye ẹ̀ṣẹ si ni: li arin awọn ẹ̀ya ara wa, li ahọn ti mba gbogbo ara jẹ́ ti o si ntinabọ ipa aiye wa; ọrun apãdi si ntinabọ on na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Iná sì ni ahọ́n, ayé ẹ̀ṣẹ̀ sì ni: ní àárin àwọn ẹ̀yà-ara wa, ní ahọ́n ti ń bá gbogbo ara jẹ́, tí yóò sì ti iná bọ ipa ayé wa; ọ̀run àpáàdì a sì tiná bọ òun náà.