Jeremiah 1:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo ti fi ọ́ ṣe orí fún àwọn orílẹ̀-èdè ati ìjọba lónìí, láti fà wọ́n tu ati láti bì wọ́n lulẹ̀, láti pa wọ́n run ati láti bì wọ́n ṣubú, láti tún wọn kọ́ ati láti gbé wọn ró.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o, li oni yi ni mo fi ọ ṣe olori awọn orilẹ-ède, ati olori ijọba wọnni, lati fàtu, ati lati fà lulẹ; lati parun, ati lati wó lulẹ; lati kọ́, ati lati gbìn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wòó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀ èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti má a kọ́, àti láti máa gbìn.