Jeremiah 1:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé mò ń pe gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìjọba àríwá, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, àwọn ọba wọn yóo sì tẹ́ ìtẹ́ wọn kalẹ̀ ní ẹnubodè Jerusalẹmu, ati yíká odi gbogbo ìlú Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sa wò o, Emi o pè gbogbo idile awọn ijọba ariwa, li Oluwa wi, nwọn o si wá: olukuluku wọn o si tẹ́ itẹ rẹ̀ li ẹnu-bode Jerusalemu, ati lori gbogbo odi rẹ̀ yikakiri, ati lori gbogbo ilu Juda.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè àríwá níjà,” ni OLÚWA wí. Àwọn Ọba wọn yóò wá gbé ìtẹ́ wọn ró ní ojú-ọ̀nà à bá wọlé Jérúsálẹ́mù. Wọn ó sì dìde sí gbogbo àyíká wọn àti sí gbogbo àwọn ìlú Júdà.