Jeremiah 1:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo dá wọn lẹ́jọ́ nítorí gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, tí wọn ń sun turari fún àwọn oriṣa, tí wọ́n sì ń bọ ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si sọ̀rọ idajọ mi si wọn nitori gbogbo buburu wọn; ti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, ti nwọn ti sun turari fun ọlọrun miran, ti nwọn si tẹriba fun iṣẹ ọwọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sì kéde ìdájọ́ mi lórí àwọn ènìyàn mi nítorí ìwà búburú wọn nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀, nípa rírúbọ sí Ọlọ́run mìíràn àti sínsin àwọn ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe.