Jeremiah 1:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn, ìwọ dìde, di àmùrè rẹ, kí o sì sọ gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ fún wọn. Má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn ó bà ọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo dẹ́rù bà ọ́ níwájú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn iwọ di ẹ̀gbẹ́ rẹ li amure, ki o si dide, ki o si wi fun wọn gbogbo ohun ti emi o pa laṣẹ fun ọ, má fòya niwaju wọn, ki emi ki o má ba mu ọ dãmu niwaju wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pa lásẹ fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí wọn dẹ́rù bà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn.