Jeremiah 1:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wò ó, mo ti sọ ọ́ di ìlú tí a mọ odi yíká lónìí, o di òpó irin ati ògiri tí a fi bàbà mọ fún gbogbo ilẹ̀ yìí, ati fún àwọn ọba ilẹ̀ Juda, àwọn ìjòyè, ati àwọn alufaa rẹ̀, ati àwọn eniyan ilẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sa wò o, loni ni mo fi ọ ṣe ilu-odi, ati ọwọ̀n irin, ati odi idẹ fun gbogbo ilẹ; fun awọn ọba Juda, awọn ijoye rẹ̀, awọn alufa, ati enia ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní òní èmi ti sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè alágbára, òpó ìrin àti odi idẹ sí àwọn Ọba Júdà, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.