Jeremiah 1:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó sì tún gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA ní ìgbà ayé Jehoiakimu, ọmọ Josaya, ọba Juda títí di òpin ọdún kọkanla tí Sedekaya ọmọ Josaya jọba ní ilẹ̀ Juda, títí tí ogun fi kó Jerusalẹmu ní oṣù karun-un ọdún náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si tọ̀ ọ wá pẹlu ni igba ọjọ Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, titi de opin ọdun kọkanla Sedekiah, ọmọ Josiah, ọba Juda, ani de igba ti a kó Jerusalemu lọ ni igbekun li oṣu karun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti títí dé àsìkò Jéhóákímù ọmọ Jòṣáyà Ọba Júdà, títí dé oṣù kaàrún ọdún kọkànlá Ṣedekáyà ọmọ Jòṣáyà Ọba Júdà, nígbà tí àwọn ará Jérúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn.