Jeremiah 1:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn OLUWA dá mi lóhùn, ó ní, “Má pe ara rẹ ní ọmọde, nítorí pé gbogbo ẹni tí mo bá rán ọ sí ni o gbọdọ̀ tọ̀ lọ. Gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ ni o gbọdọ̀ sọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Oluwa wi fun mi pe, má wipe, ọmọde li emi: ṣugbọn iwọ o lọ sọdọ ẹnikẹni ti emi o ran ọ si, ati ohunkohun ti emi o paṣẹ fun ọ ni iwọ o sọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sọ fún mi pé, má ṣe sọ pé ọmọdé lásán ni mí. O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ.