Jeremiah 10:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ó bá fọhùn, omi á máa rọ́kẹ̀kẹ̀ lójú ọ̀run, ó mú kí ìkùukùu gbéra láti òpin ayé, òun ni ó dá mànàmáná fún òjò, tí ó sì mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o ba sán ãrá, ọ̀pọlọpọ omi ni mbẹ loju-ọrun, o si jẹ ki kũku rú soke lati opin aiye; o da mànamana fun òjo, o si mu ẹfũfu jade lati inu iṣura rẹ̀ wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omi lọ́run a sì pariwo, ó mú kí ìkuùkù ru sókè láti òpin ayé: ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò, ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.