Jeremiah 10:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí OLUWA wí pé, “Mo ṣetán wàyí, tí n óo sọ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí nù bí òkò. N óo mú kí ìpọ́njú dé bá wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé nǹkan ṣe àwọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o gbọ̀n awọn olugbe ilẹ na nù lẹ̃kan yi, emi o si pọ́n wọn loju, ki nwọn ki o le ri i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí ni OLÚWA wí: “Ní àkókò yìí, èmi yóò gbọn àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ náà jáde. Èmi yóò mú ìpọ́njú bá wọn, kí wọn kí ó lè rí wọn mú.”