Jeremiah 10:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àgọ́ mi ti wó, gbogbo okùn rẹ̀ sì ti já. Àwọn ọmọ mi ti fi mí sílẹ̀, wọn kò sì sí mọ́. Kò sí ẹni tí yóo máa bá mi pa àgọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóo máa bá mi ta aṣọ àgọ́ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Agọ mi bajẹ, gbogbo okùn mi si ja: awọn ọmọ mi ti fi mi silẹ lọ, nwọn kò sí mọ́, kò si ẹnikan ti yio nà agọ mi mọ, ti yio si ta aṣọ ikele mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àgọ́ mi bàjẹ́, gbogbo okùn rẹ̀ sì já. Àwọn ọmọ mi ti lọ lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́ Kò sí ẹnìkankan pẹ̀lú mi mọ́, báyìí kò sí ẹni tí yóò ná àgọ́ mi tàbí ṣe ibùgbé fún mi