Jeremiah 10:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé òmùgọ̀ ni àwọn olùṣọ́-aguntan, wọn kò sì ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA, nítorí náà wọn kò ṣe àṣeyọrí, tí gbogbo agbo wọn sì fi túká.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori awọn oluṣọ agutan ti di ope, nwọn kò si wá Oluwa: nitorina nwọn kì yio ri rere, gbogbo agbo wọn yio si tuka.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn olùsọ́ àgùntàn jẹ́ aláìlóye, wọn kò sì wá OLÚWA: nítorí náà wọn kì yóò ṣe rere àti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká.